Luk 21:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI o si gbé oju soke, o ri awọn ọlọrọ̀ nfi ẹ̀bun wọn sinu apoti iṣura.

2. O si ri talakà opó kan pẹlu, o nsọ owo-idẹ wẹ́wẹ meji sibẹ.

3. O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, talakà opó yi fi si i jù gbogbo wọn lọ:

4. Nitori gbogbo awọn wọnyi fi sinu ẹ̀bun Ọlọrun lati ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aìni rẹ̀ o sọ gbogbo ohun ini rẹ̀ ti o ni sinu rẹ̀.

5. Bi awọn kan si ti nsọ̀rọ ti tẹmpili, bi a ti fi okuta daradara ati ẹ̀bun ṣe e li ọṣọ, o ní,

Luk 21