22. O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?
23. Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò?
24. Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni.
25. O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
26. Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́.
27. Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i,
28. Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀.
29. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ.
30. Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ.
31. Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú.
32. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
33. Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya.
34. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni.