11. O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
12. O si tún rán ẹkẹta: nwọn si ṣá a lọgbẹ pẹlu, nwọn si tì i jade.
13. Nigbana li oluwa ọgba ajara wipe, Ewo li emi o ṣe? emi o rán ọmọ mi ayanfẹ lọ: bọya nigbati nwọn ba ri i, nwọn o ṣojuṣaju fun u.
14. Ṣugbọn nigbati awọn àgbẹ na ri i, nwọn ba ara wọn gbèro pe, Eyi li arole: ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki ogún rẹ̀ ki o le jẹ ti wa.
15. Bẹ̃ni nwọn si ti i jade sẹhin ọgba ajara, nwọn si pa a. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe si wọn?
16. Yio wá, yio si pa awọn àgbẹ wọnni run, yio si fi ọgba ajara na fun awọn ẹlomiran. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn ni, Ki a má ri i.
17. Nigbati o si wò wọn, o ni, Ewo ha li eyi ti a ti kọwe pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li a sọ di pàtaki igun ile?