Luk 2:50-52 Yorùbá Bibeli (YCE)

50. Ọrọ ti o sọ kò si yé wọn.

51. O si ba wọn sọkalẹ lọ si Nasareti, o si fi ara balẹ fun wọn: ṣugbọn iya rẹ̀ pa gbogbo nkan wọnyi mọ́ ninu ọkàn rẹ̀.

52. Jesu si npọ̀ li ọgbọ́n, o si ndàgba, o si wà li ojurere li ọdọ Ọlọrun ati enia.

Luk 2