5. Lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya rẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyún.
6. O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí.
7. O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro.
8. Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé.
9. Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi.
10. Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo.