22. Nigbati ọjọ iwẹnu Maria si pé gẹgẹ bi ofin Mose, nwọn gbé Jesu wá si Jerusalemu lati fi i fun Oluwa;
23. (Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;)
24. Ati lati rubọ gẹgẹ bi eyi ti a wi ninu ofin Oluwa, Àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji.
25. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e.
26. A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa.
27. O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin.
28. Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni,
29. Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ:
30. Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na,
31. Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo;
32. Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.