Luk 18:38-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

38. O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

39. Awọn ti nlọ niwaju ba a wi pe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i kunkun pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.

40. Jesu si dẹṣẹ duro, o ni, ki a mu u tọ̀ on wá: nigbati o si sunmọ ọ, o bi i,

Luk 18