32. Nitori a o fi i le awọn Keferi lọwọ, a o fi i ṣe ẹlẹyà, a o si fi i ṣe ẹsin, a o si tutọ́ si i lara:
33. Nwọn o si nà a, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.
34. Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.
35. O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe:
36. Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si.
37. Nwọn si wi fun u pe, Jesu ti Nasareti li o nkọja lọ.
38. O si kigbe pe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.