Luk 15:13-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.

14. Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini.

15. O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ.

16. Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u.

Luk 15