Luk 15:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.

2. Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun.

3. O si pa owe yi fun wọn, wipe.

4. Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i?

5. Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ.

6. Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù.

7. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.

8. Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i?

9. Nigbati o si ri i, o pè awọn ọrẹ́ ati awọn aladugbo rẹ̀ jọ, o wipe, Ẹ ba mi yọ̀; nitori mo ri fadakà ti mo ti sọnù.

10. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.

11. O si wipe, ọkunrin kan li ọmọkunrin meji:

12. Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn.

13. Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.

Luk 15