Luk 13:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn.

2. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni?

3. Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.

4. Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ?

5. Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ.

6. O si pa owe yi fun wọn pe; ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan.

Luk 13