2. Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀.
3. Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.
4. Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́.
5. Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru.
6. Ologoṣẹ marun ki a ntà li owo idẹ wẹ́wẹ meji? a kò si gbagbé ọkan ninu wọn niwaju Ọlọrun?
7. Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ki ẹ máṣe bẹ̀ru: ẹnyin ni iye lori jù ologoṣẹ pipọ lọ.