Luk 10:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de.

2. O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀.

Luk 10