Lef 8:31-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ.

32. Eyiti o ba si kù ninu ẹran na ati ninu àkara na ni ki ẹnyin ki o fi iná sun.

33. Ki ẹnyin ki o máṣe jade si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ni ijọ́ meje, titi ọjọ́ ìyasimimọ́ nyin yio fi pé; nitori ijọ́ meje ni a o fi yà nyin simimọ́.

34. Bi o ti ṣe li oni yi, bẹ̃li OLUWA fi aṣẹ lelẹ lati ṣe, lati ṣètutu fun nyin.

35. Nitorina ni ki ẹnyin ki o joko nibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, li ọsán ati li oru ni ijọ́ meje, ki ẹnyin ki o si ma pa aṣẹ OLUWA mọ́, ki ẹnyin ki o má ba kú: nitoripe bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.

36. Bẹ̃li Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo ti OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ lati ọwọ́ Mose wá.

Lef 8