Lef 8:12-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. O si dà ninu oróro itasori si ori Aaroni, o si ta a si i lara, lati yà a simimọ́.

13. Mose si mú awọn ọmọ Aaroni wá, o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn, o si fi amure di wọn, o si fi fila dé wọn li ori; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

14. O si mú akọmalu wá fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ fọwọ́ wọn lé ori akọmalu na fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

15. O si pa a; Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si fi iká rẹ̀ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na yiká, o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ, o si yà a simimọ́, lati ṣètutu fun u.

16. O si mú gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, Mose si sun u lori pẹpẹ.

17. Ṣugbọn akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀, on li o fi iná sun lẹhin ibudó; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

18. O si mú àgbo ẹbọ sisun wá: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.

19. O si pa a: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.

20. O si kun àgbo na; Mose si sun ori rẹ̀, ati ara rẹ̀, ati ọrá na.

21. O si ṣìn ifun rẹ̀ ati itan rẹ̀ ninu omi; Mose si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ: ẹbọ sisun fun õrùn didùn ni: ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

22. O si mú àgbo keji wá, àgbo ìyasimimọ́: Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ si fọwọ́ wọn lé ori àgbo na.

23. O si pa a; Mose si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀.

24. O si mú awọn ọmọ Aaroni wá, Mose si tọ́ ninu ẹ̀jẹ na si eti ọtún wọn, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn: Mose si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ yiká.

25. O si mú ọrá na, ati ìru ti o lọrá, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, ati iwe mejeji, ati ọrá wọn, ati itan ọtún:

26. Ati lati inu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA, o mú adidùn àkara alaiwu kan, ati adidùn àkara oloróro kan, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan, o si fi wọn sori ọrá nì, ati si itan ọtún na:

27. O si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni li ọwọ́, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀, o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

28. Mose si gbà wọn li ọwọ́ wọn, o si sun wọn lori pẹpẹ li ẹbọ sisun: ìyasimimọ́ ni nwọn fun õrùn didùn: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

29. Mose si mú igẹ̀ ẹran na, o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA: nitori ipín ti Mose ni ninu àgbo ìyasimimọ́; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

30. Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.

31. Mose si wi fun Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ bọ̀ ẹran na li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin si jẹ ẹ pẹlu àkara nì ti mbẹ ninu agbọ̀n ìyasimimọ́, bi mo ti fi aṣẹ lelẹ wipe, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ ni ki o jẹ ẹ.

Lef 8