13. Ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀ li ọkan ninu wọnyi, a o si dari rẹ̀ jì i: iyokù si jẹ́ ti alufa, bi ẹbọ ohunjijẹ.
14. OLUWA si sọ fun Mose pe,
15. Bi ẹnikan ba ṣìṣe, ti o ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀ ninu ohun mimọ́ OLUWA; nigbana ni ki o múwa fun OLUWA nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran wá, ni idiyele rẹ nipa ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
16. Ki o si ṣe atunṣe nitori ibi ti o ti ṣe ninu ohun mimọ́, ki o si fi idamarun pẹlu rẹ̀, ki o si fi i fun alufa: alufa yio si fi àgbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ṣètutu fun u, a o si dari rẹ̀ jì i.
17. Bi ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o ba si ṣe ọkan ninu nkan wọnyi, eyiti ofin OLUWA kọ̀ lati ṣe; bi kò tilẹ mọ̀, ṣugbọn o jẹbi, yio si rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.