13. Bi gbogbo ijọ enia Israeli ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, ti ohun na si pamọ́ li oju ijọ, ti nwọn si ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA, ti a ki ba ṣe, ti nwọn si jẹbi;
14. Nigbati ẹ̀ṣẹ ti nwọn ba ti ṣẹ̀ si i, ba di mimọ̀, nigbana ni ki ijọ enia ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá nitori ẹ̀ṣẹ na, ki nwọn ki o si mú u wá siwaju agọ́ ajọ.
15. Ki awọn àgbagba ijọ enia ki o fi ọwọ́ wọn lé ori akọmalu na niwaju OLUWA: ki a si pa akọmalu na niwaju OLUWA.
16. Ki alufa ti a fi oróro yàn ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na wá si agọ́ ajọ:
17. Ki alufa na ki o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si wọ́n ọ nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele.
18. Ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ti mbẹ ninu agọ́ ajọ, ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
19. Ki o si mú gbogbo ọrá rẹ̀ lara rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ.
20. Ki o si fi akọmalu na ṣe; bi o ti fi akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ṣe, bẹ̃ni ki o si fi eyi ṣe: ki alufa na ki o si ṣètutu fun wọn, a o si dari rẹ̀ jì wọn.
21. Ki o si gbé akọmalu na jade lọ sẹhin ibudó, ki o si sun u bi o ti sun akọmalu iṣaju: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni fun ijọ enia.
22. Nigbati ijoye kan ba ṣẹ̀, ti o si fi aimọ̀ rú ọkan ninu ofin OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ti a ki ba rú, ti o si jẹbi;
23. Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ninu eyiti o ti ṣẹ̀, ba di mímọ̀ fun u; ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, akọ alailabùku:
24. Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ewurẹ na, ki o si pa a ni ibiti nwọn gbé npa ẹbọ sisun niwaju OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
25. Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun.