Lef 23:41-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje.

42. Ki ẹnyin ki o ma gbé inu agọ́ ni ijọ́ meje; gbogbo ibilẹ ni Israeli ni ki o gbé inu agọ́:

43. Ki iran-iran nyin ki o le mọ̀ pe, Emi li o mu awọn ọmọ Israeli gbé inu agọ́, nigbati mo mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

44. Mose si sọ gbogbo ajọ OLUWA wọnyi fun awọn ọmọ Israeli.

Lef 23