Lef 23:27-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ijọ́ kẹwa oṣù keje yi ni ki o ṣe ọjọ́ ètutu: ki apejọ mimọ́ wà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹ si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

28. Ẹnyin kò si gbọdọ ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi: nitoripe ọjọ́ ètutu ni, lati ṣètutu fun nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin.

29. Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

30. Ati ọkànkọkan ti o ba ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi, ọkàn na li emi o run kuro lãrin awọn enia rẹ̀.

31. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: ki o jẹ́ ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

32. Ọjọ́-isimi ni fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọn ọkàn nyin loju: lo ọjọ́ kẹsan oṣù na li alẹ, lati alẹ dé alẹ, ni ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́-isimi nyin mọ́.

33. OLUWA si sọ fun Mose pe,

34. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA.

Lef 23