15. Lati ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi, ni ọjọ́ ti ẹnyin mú ìdi-ọkà ẹbọ fifì nì wá, ki ẹnyin ki o si kà ọjọ́-isimi meje pé;
16. Ani di ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi keje, ki ẹnyin ki o kà ãdọta ọjọ́; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ titun si OLUWA.
17. Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA.
18. Pẹlu àkara na ki ẹnyin ki o si fi ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabukù rubọ, ati ẹgbọrọ akọmalu kan, ati àgbo meji: ki nwọn ki o jẹ́ ẹbọ sisun si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe olõrùn didùn ni si OLUWA.
19. Nigbana ni ki ẹnyin ki o fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan ru ẹbọ alafia.
20. Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na.
21. Ki ẹnyin ki o si kede li ọjọ́ na gan; ki o le jẹ́ apejọ mimọ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: yio si ma ṣe ìlana fun nyin titilai ni ibujoko nyin gbogbo ni iran-iran nyin.
22. Nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa ẹba oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pèṣẹ́ ikore rẹ̀: ki iwọ ki o fi i silẹ fun awọn talaka, ati fun alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
23. OLUWA si sọ fun Mose pe,
24. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù ni ki ẹnyin ki o ní isimi; iranti ifunpe, apejọ mimọ́.
25. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: bikoṣepe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.