Lef 23:1-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, ajọ OLUWA, ti ẹnyin o pè fun apejọ mimọ́, wọnyi li ajọ mi.

3. Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ: ṣugbọn ni ijọ́ keje li ọjọ́ isimi, apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ kan ninu rẹ̀: nitoripe ọjọ́-isimi OLUWA ni ninu ibujoko nyin gbogbo.

4. Wọnyi li ajọ OLUWA, ani apejọ mimọ́, ti ẹnyin o pè li akokò wọn.

5. Ni ijọ́ kẹrinla oṣù kini, li aṣalẹ, li ajọ irekọja OLUWA.

6. Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na li ajọ àkara alaiwu si OLUWA: ijọ́ meje li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.

7. Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara ninu rẹ̀.

8. Bikoṣe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni ijọ́ meje: ni ijọ́ keje ni apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara.

9. OLUWA si sọ fun Mose pe,

10. Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, ti ẹnyin o si ma ṣe ikore rẹ̀, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ìdi-ọkà kan akọ́so ikore nyin tọ̀ alufa wá:

11. On o si fì ìdi-ọkà na niwaju OLUWA, lati ṣe itẹwọgbà fun nyin: ni ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi ni ki alufa ki o fì i.

12. Li ọjọ́ ti ẹnyin fì ìdi-ọkà ni ki ẹnyin ki o rubọ akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan alailabùku fun ẹbọ sisun si OLUWA.

13. Ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ ki o jẹ́ meji idamẹwa òṣuwọn iyẹfun daradara, ti a fi oróro pò, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA fun õrun didùn: ati ẹbọ ohun-mimu rẹ̀ ni ki o ṣe ọtí-waini idamẹrin òṣuwọn hini.

14. Ẹnyin kò si gbọdọ jẹ àkara, tabi ọkà yiyan, tabi ọkà tutù ninu ipẹ́, titi yio fi di ọjọ́ na gan ti ẹnyin mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ Ọlọrun nyin wá: ki o si jasi ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.

15. Lati ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi, ni ọjọ́ ti ẹnyin mú ìdi-ọkà ẹbọ fifì nì wá, ki ẹnyin ki o si kà ọjọ́-isimi meje pé;

16. Ani di ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi keje, ki ẹnyin ki o kà ãdọta ọjọ́; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ titun si OLUWA.

17. Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA.

Lef 23