Lef 22:30-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Li ọjọ́ na ni ki a jẹ ẹ; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ́kù silẹ ninu rẹ̀ titi di ijọ́ keji: Emi li OLUWA.

31. Nitorina ni ki ẹnyin ki o ma pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.

32. Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bà orukọ mimọ́ mi jẹ́; bikoṣe ki a yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́,

33. Ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi li OLUWA.

Lef 22