Lef 22:25-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin.

26. OLUWA si sọ fun Mose pe,

27. Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

28. Ibaṣe abomalu tabi agutan, ẹnyin kò gbọdọ pa a ati ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ kanna.

29. Nigbati ẹnyin ba si ru ẹbọ ọpẹ́ si OLUWA, ẹ ru u ki o le dà.

Lef 22