Lef 20:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

8. Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́.

9. Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀.

10. Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ.

11. Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.

12. Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn.

13. Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.

14. Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin.

15. Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na.

Lef 20