2. Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa.
3. Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́.
4. Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a:
5. Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn.
6. Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
7. Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
8. Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́.
9. Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀.
10. Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ.
11. Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
12. Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn.