Lef 19:24-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ṣugbọn li ọdún kẹrin, gbogbo eso rẹ̀ na ni yio jẹ́ mimọ́, si ìyin OLUWA.

25. Ati li ọdún karun ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu eso rẹ̀, ki o le ma mú ibisi rẹ̀ wá fun nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

26. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohun kan ti on ti ẹ̀jẹ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe ifaiya, tabi ṣe akiyesi ìgba.

27. Ẹnyin kò gbọdọ gẹ̀ ori nyin, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tọ́ irungbọn rẹ.

28. Ẹnyin kò gbọdọ sín gbẹ́rẹ kan si ara nyin nitori okú, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ kọ àmi kan si ara nyin: Emi li OLUWA.

29. Máṣe bà ọmọ rẹ obinrin jẹ́, lati mu u ṣe àgbere; ki ilẹ na ki o má ba di ilẹ àgbere, ati ki ilẹ na má ba kún fun ìwabuburu.

30. Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA.

31. Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

32. Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA.

33. Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara.

34. Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

35. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu.

36. Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá.

Lef 19