Lef 18:5-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA.

6. Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA.

7. Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

8. Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni.

9. Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú.

10. Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.

11. Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.

Lef 18