12. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni.
13. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni.
14. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni.
15. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
16. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.
17. Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.
18. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.
19. Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.
20. Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.
21. Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
22. Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni.
23. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni.