Lef 17:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitoripe ẹmi ara mbẹ ninu ẹ̀jẹ: emi si ti fi i fun nyin lati ma fi ṣètutu fun ọkàn nyin lori pẹpẹ nì: nitoripe ẹ̀jẹ ni iṣe ètutu fun ọkàn.

12. Nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọkàn kan ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ, bẹ̃li alejò kan ti nṣe atipo ninu nyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ.

13. Ati ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ninu wọn, ti nṣe ọdẹ ti o si mú ẹranko tabi ẹiyẹ ti a ba jẹ; ani ki o ro ẹ̀jẹ rẹ̀ dànu, ki o si fi erupẹ bò o.

14. Nitoripe ẹmi gbogbo ara ni, ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ẹmi rẹ̀: nitorina ni mo ṣe wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ẹ̀jẹ ẹrankẹran: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi ara gbogbo: ẹnikẹni ti o ba jẹ ẹ li a o ke kuro.

15. Ati gbogbo ọkàn ti o ba jẹ ẹran ti o tikara rẹ̀ kú, tabi eyiti a fàya, iba ṣe ọkan ninu awọn ibilẹ, tabi alejò, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: nigbana li on o mọ́.

16. Ṣugbọn bi kò ba fọ̀ wọn, tabi ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀; njẹ on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

Lef 17