Lef 16:17-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ki o má si sí ẹnikan ninu agọ́ ajọ nigbati o ba wọle lati ṣètutu ninu ibi mimọ́, titi yio fi jade, ti o si ti ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ati fun gbogbo ijọ enia Israeli.

18. Ki o si jade si ibi pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ki o si ṣètutu si i; ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ati ninu ẹ̀jẹ ewurẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ na yiká.

19. Ki o si fi ika rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na wọ́n ara rẹ̀ nigba meje, ki o si wẹ̀ ẹ mọ́, ki o si yà a simimọ́ kuro ninu aimọ́ awọn ọmọ Israeli.

20. Nigbati o ba si pari ati ṣètutu si ibi mimọ́, ati si agọ́ ajọ, ati pẹpẹ, ki o mú ewurẹ alãye nì wá:

21. Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alãye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù:

22. Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù.

23. Ki Aaroni ki o si wá sinu agọ́ ajọ, ki o si bọ́ aṣọ ọ̀gbọ wọnni silẹ, ti o múwọ̀ nigbati o wọ̀ ibi mimọ́ lọ, ki o si fi wọn sibẹ̀:

24. Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia.

25. Ọrá ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì ni ki o si sun lori pẹpẹ.

26. Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.

27. Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná.

28. Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.

29. Eyi ni ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin: pe li oṣù keje, li ọjọ́ kẹwa oṣù, ni ki ẹnyin ki o pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹnyin má si ṣe iṣẹ kan rára, iba ṣe ibilẹ, tabi alejò ti nṣe atipo lãrin nyin:

Lef 16