Lef 16:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose lẹhin ikú awọn ọmọ Aaroni meji, nigbati nwọn rubọ niwaju OLUWA, ti nwọn si kú;

2. OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu.

3. Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun.

4. Ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ mimọ́ wọ̀, ki o si bọ̀ ṣòkoto ọ̀gbọ nì si ara rẹ̀, ki a si fi amure ọ̀gbọ kan dì i, fila ọ̀gbọ ni ki a fi ṣe e li ọṣọ́: aṣọ mimọ́ ni wọnyi; nitorina ni o ṣe wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si mú wọn wọ̀.

5. Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli.

6. Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀.

7. Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

8. Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ).

9. Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

10. Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.

11. Ki Aaroni ki o si mú akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá, ti iṣe ti on tikararẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ki o si pa akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti iṣe fun ara rẹ̀:

12. Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele:

13. Ki o si fi turari na sinu iná niwaju OLUWA, ki ẽfin turari ki o le bò itẹ́-ãnu ti mbẹ lori ẹri, ki on ki o má ba kú.

14. Ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si fi ika rẹ̀ wọn ọ sori itẹ́-ãnu ni ìha ìla-õrùn; ati niwaju itẹ́-ãnu ni ki o fi ìka rẹ̀ wọ́n ninu ẹ̀jẹ na nigba meje.

15. Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu:

16. Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́ nì, nitori aimọ́ awọn ọmọ Israeli, ati nitori irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn: bẹ̃ni ki o si ṣe si agọ́ ajọ, ti mbẹ lọdọ wọn ninu aimọ́ wọn.

17. Ki o má si sí ẹnikan ninu agọ́ ajọ nigbati o ba wọle lati ṣètutu ninu ibi mimọ́, titi yio fi jade, ti o si ti ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ati fun gbogbo ijọ enia Israeli.

18. Ki o si jade si ibi pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ki o si ṣètutu si i; ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ati ninu ẹ̀jẹ ewurẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ na yiká.

Lef 16