52. Ki o si fi ẹ̀jẹ ẹiyẹ na wẹ̀ ile na mọ́, ati pẹlu omi ṣiṣàn nì, ati pẹlu ẹiyẹ alãye nì, ati pẹlu igi opepe nì, ati pẹlu ewe-hissopu nì, ati pẹlu ododó:
53. Ṣugbọn ki o jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ kuro ninu ilu lọ sinu gbangba oko, ki o si ṣètutu si ile na: yio si di mimọ́.
54. Eyi li ofin fun gbogbo onirũru àrun ẹ̀tẹ, ati ipẹ́;
55. Ati fun ẹ̀tẹ aṣọ, ati ti ile;
56. Ati fun wiwu, ati fun apá, ati fun àmi didán:
57. Lati kọni nigbati o ṣe alaimọ́, ati nigbati o ṣe mimọ́: eyi li ofin ẹ̀tẹ.