Lef 14:21-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Bi o ba si ṣe talaka, ti kò le mú tobẹ̃ wá, njẹ ki o mú akọ ọdọ-agutan kan wá fun ẹbọ ẹbi lati fì, lati ṣètutu fun u, ati ọkan ninu idamẹwa òṣuwọn deali iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ, ati òṣuwọn logu oróro kan;

22. Ati àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji, irú eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to; ki ọkan ki o si ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ki ekeji ki o si ṣe ẹbọ sisun.

23. Ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá ni ijọ́ kẹjọ fun ìwẹnumọ́ rẹ̀, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, niwaju OLUWA.

24. Ki alufa ki o si mú ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ati òṣuwọn logu oróro, ki alufa ki o si fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

25. Ki o si pa ọdọ-agutan ẹbọ ẹbi, ki alufa ki o si mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi na, ki o si fi i si etí ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀.

26. Ki alufa ki o si dà ninu oróro na si atẹlẹwọ òsi ara rẹ̀:

27. Ki alufa ki o si fi iká rẹ̀ ọtún ta ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ òsi rẹ̀ nigba meje niwaju OLUWA:

28. Ki alufa ki o si fi ninu oróro na ti mbẹ li ọwọ́ rẹ̀ si eti ọtún ẹniti a o wẹ̀numọ́, ati si àtampako ọwọ́ ọtún rẹ̀, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún rẹ̀, si ibi ẹ̀jẹ ẹbọ ẹbi:

29. Ati oróro iyokù ti mbẹ li ọwọ́ alufa ni ki o fi si ori ẹniti a o wẹ̀numọ́, lati ṣètutu fun u niwaju OLUWA.

30. Ki o si fi ọkan ninu àdaba nì rubọ, tabi ọkan ninu ọmọ ẹiyẹle nì, iru eyiti ọwọ́ rẹ̀ ba to:

31. Ani irú eyiti apa rẹ̀ ka, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ: ki alufa ki o si ṣètutu fun ẹniti a o wẹ̀numọ́ niwaju OLUWA.

32. Eyi li ofin rẹ̀ li ara ẹniti àrun ẹ̀tẹ wà, apa ẹniti kò le ka ohun ìwẹnumọ́ rẹ̀.

Lef 14