Lef 13:53-59 Yorùbá Bibeli (YCE)

53. Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na kò ba tàn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe;

54. Nigbana ni ki alufa ki o paṣẹ ki nwọn ki o fọ̀ ohun na ninu eyiti àrun na gbé wà, ki o si sé e mọ́ ni ijọ meje si i.

55. Ki alufa ki o si wò àrun na, lẹhin igbati a fọ̀ ọ tán: si kiyesi i, bi àrun na kò ba pa awọ rẹ̀ dà, ti àrun na kò si ràn si i, alaimọ́ ni; ninu iná ni ki iwọ ki o sun u; o kẹ̀ ninu, iba gbo ninu tabi lode.

56. Bi alufa ba si wò, si kiyesi i, ti àrun na ba ṣe bi ẹni wodú lẹhin igbati o ba fọ̀ ọ tán; nigbana ni ki o fà a ya kuro ninu aṣọ na, tabi ninu awọ na, tabi ninu ita, tabi ninu iwun:

57. Bi o ba si hàn sibẹ̀ ninu aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo kan ti a fi awọ ṣe, àrun riràn ni: ki iwọ ki o fi iná sun ohun ti àrun na wà ninu rẹ̀.

58. Ati aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunkohun ti a fi awọ ṣe, ti iwọ ba fọ̀, bi àrun na ba wọ́n kuro ninu wọn nigbana ni ki a tun fọ̀ ọ lẹkeji, on o si jẹ́ mimọ́.

59. Eyi li ofin àrun ẹ̀tẹ, ninu aṣọ, kubusu tabi ti ọ̀gbọ, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ohunkohun èlo awọ kan, lati pè e ni mimọ́, tabi lati pè e li aimọ́.

Lef 13