47. Ati aṣọ ti àrun ẹ̀tẹ mbẹ ninu rẹ̀, iba ṣe aṣọ kubusu, tabi aṣọ ọ̀gbọ;
48. Iba ṣe ni ita, tabi ni iwun; ti ọ̀gbọ, tabi ti kubusu; iba ṣe li awọ, tabi ohun kan ti a fi awọ ṣe;
49. Bi àrun na ba ṣe bi ọbẹdo tabi bi pupa lara aṣọ na, tabi lara awọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu ohunèlo awọ kan; àrun ẹ̀tẹ ni, ki a si fi i hàn alufa:
50. Ki alufa ki o si wò àrun na, ki o si sé ohun ti o ní àrun na mọ́ ni ijọ́ meje:
51. Ki o si wò àrun na ni ijọ́ keje: bi àrun na ba ràn sara aṣọ na, iba ṣe ni ita, tabi ni iwun, tabi ninu awọ, tabi ninu ohun ti a fi awọ ṣe; àrun oun ẹ̀tẹ kikẹ̀ ni; alaimọ́ ni.