9. Wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti mbẹ ninu omi: ohunkohun ti o ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, ninu okun, ati ninu odò, awọn ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
10. Ati gbogbo eyiti kò ní lẹbẹ ati ipẹ́ li okun, ati li odò, ninu gbogbo ohun ti nrá ninu omi, ati ninu ohun alãye kan ti mbẹ ninu omi, irira ni nwọn o jasi fun nyin,
11. Ani irira ni nwọn o ma jẹ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu ẹran wọn, okú wọn ni ẹ o sì kàsi irira.
12. Ohunkohun ti kò ba ní lẹbẹ ati ipẹ́, ninu omi, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun.
13. Wọnyi li ẹnyin o si ma kàsi irira ninu ẹiyẹ; awọn li a kò gbọdọ jẹ, irira ni nwọn iṣe: idì, ati aṣá-idì, ati idì-ẹja.
14. Ati igún, ati aṣá li onirũru rẹ̀;
15. Ati gbogbo ìwo li onirũru rẹ̀;
16. Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀,
17. Ati òyo ati ìgo, ati owiwi;
18. Ati ogbugbu, ati ofù, ati àkala;
19. Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.
20. Gbogbo ohun ti nrakò, ti nfò ti o si nfi mẹrẹrin rìn ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin.
21. Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹnyin ki o ma jẹ ninu gbogbo ohun ti nfò, ti nrakò, ti nfi gbogbo mẹrẹrin rìn, ti o ní tete lori ẹsẹ̀ wọn, lati ma fi ta lori ilẹ;
22. Ani ninu wọnyi ni ki ẹnyin ma jẹ; eṣú ni irú rẹ̀, ati eṣú onihoho nipa irú rẹ̀, ati ọbọnbọn nipa irú rẹ̀, ati ẹlẹnga nipa irú rẹ̀.
23. Ṣugbọn gbogbo ohun iyokù ti nfò ti nrakò, ti o ní ẹsẹ̀ mẹrin, on ni ki ẹnyin kàsi irira fun nyin.