Lef 11:42-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn.

43. Ẹnyin kò gbọdọ fi ohun kan ti nrakò, sọ ara nyin di irira, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi wọn sọ ara nyin di alaimọ́ ti ẹnyin o fi ti ipa wọn di elẽri.

44. Nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin si mimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́; nitoripe mimọ́ li Emi: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fi ohunkohun ti nrakò sọ ara nyin di elẽri.

Lef 11