Lef 11:26-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Ẹranko gbogbo ti o yà bàta-ẹsẹ̀, ti kò si là ẹsẹ̀, tabi ti kò si jẹ apọjẹ, ki o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: gbogbo ẹniti o ba farakàn wọn ki o jẹ́ alaimọ́.

27. Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

28. Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin.

29. Wọnyi ni yio si jasi alaimọ́ fun nyin ninu ohun ti nrakò lori ilẹ; ase, ati eku, ati awun nipa irú rẹ̀.

30. Ati ọmọ̃le, ati ahanhan, ati alãmu, ati agiliti, ati agẹmọ.

31. Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

32. Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́.

33. Ati gbogbo ohunèlo amọ̀, ninu eyiti ọkan ninu okú nwọn ba bọ́ si, ohunkohun ti o wù ki o wà ninu rẹ̀ yio di alaimọ́, ki ẹnyin ki o si fọ́ ọ.

34. Ninu onjẹ gbogbo ti a o ba jẹ, ti irú omi nì ba dà si, yio di alaimọ́: ati ohun mimu gbogbo ti a o ba mu ninu irú ohunèlo na yio di alaimọ́.

35. Ati ohunkohun lara eyiti ninu okú wọn ba ṣubulù, yio di alaimọ́; iba ṣe àro, tabí idana, wiwó ni ki a wó wọn lulẹ: alaimọ́ ni nwọn, nwọn o si jẹ́ alaimọ́ fun nyin.

36. Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́.

37. Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́.

38. Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin.

39. Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Lef 11