1. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni, o wi fun wọn pe,
2. Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Wọnyi li ẹranko ti ẹnyin o ma jẹ ninu gbogbo ẹran ti mbẹ lori ilẹ aiye.
3. Ohunkohun ti o ba yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là li ẹsẹ̀, ti o si njẹ apọjẹ, ninu ẹran, on ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.
4. Ṣugbọn wọnyi ni ki ẹ máṣe jẹ ninu awọn ti njẹ apọjẹ, tabi awọn ti o si yà bàta-ẹsẹ̀: bi ibakasiẹ, nitoriti o njẹ apọjẹ ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin.
5. Ati gara, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin.
6. Ati ehoro, nitoriti o njẹ apọjẹ, ṣugbọn kò yà bàta-ẹsẹ̀, alaimọ́ li o jasi fun nyin.
7. Ati ẹlẹdẹ̀, bi o ti yà bàta-ẹsẹ̀, ti o si là ẹsẹ̀, ṣugbọn on kò jẹ apọjẹ, alaimọ́ li o jasi fun nyin.