Lef 10:19-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Aaroni si wi fun Mose pe, Kiyesi i, li oni ni nwọn ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn ati ẹbọ sisun wọn niwaju OLUWA; irú nkan wọnyi li o si ṣubulù mi: emi iba si ti jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ li oni, o ha le dara li oju OLUWA?

20. Nigbati Mose gbọ́ eyi inu rẹ̀ si tutù.

Lef 10