Kol 3:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nitori ohun tí ibinu Ọlọrun fi mbọ̀wa sori awọn ọmọ alaigbọran.

7. Ninu eyiti ẹnyin pẹlu ti nrìn nigbakan rí, nigbati ẹnyin ti wà ninu nkan wọnyi.

8. Ṣugbọn nisisiyi, ẹ fi gbogbo wọnyi silẹ pẹlu; ibinu, irunu, arankàn, ọrọ-odi, ati ọrọ itiju kuro li ẹnu nyin.

9. Ẹ má si ṣe purọ́ fun ẹnikeji nyin, ẹnyin sa ti bọ́ ogbologbo ọkunrin nì silẹ pẹlu iṣe rẹ̀;

10. Ẹ si ti gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a sọ di titun si ìmọ gẹgẹ bi aworan ẹniti o da a:

11. Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo.

12. Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra;

13. Ẹ mã farada a fun ara nyin, ẹ si mã dariji ara nyin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sun si ẹnikan: bi Kristi ti darijì nyin, gẹgẹ bẹ̃ni ki ẹnyin ki o mã ṣe pẹlu.

14. Ati bori gbogbo nkan wọnyi, ẹ gbé ifẹ wọ̀, ti iṣe àmure ìwa pipé.

15. Ẹ si jẹ ki alafia Ọlọrun ki o mã ṣe akoso ọkàn nyin, sinu eyiti a pè nyin pẹlu ninu ara kan; ki ẹ si ma dupẹ.

16. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.

17. Ohunkohun ti ẹnyin ba si nṣe li ọ̀rọ tabi ni iṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn li orukọ Jesu Oluwa, ẹ mã fi ọpẹ́ fun Ọlọrun Baba nipasẹ rẹ̀.

18. Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi o ti yẹ ninu Oluwa.

Kol 3