Jud 1:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.

16. Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.

17. Ṣugbọn ẹnyin olufẹ, ẹ ranti awọn ọ̀rọ ti a ti sọ ṣaju lati ọwọ́ awọn Aposteli Oluwa wa Jesu Kristi;

18. Bi nwọn ti wi fun nyin pe, awọn ẹlẹgàn yio wà nigba ikẹhin, ti nwọn o mã rìn gẹgẹ bi ifẹkufẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti ara wọn.

19. Awọn wọnyi ni awọn ẹniti nya ara wọn si ọtọ, awọn ẹni ti ara, ti nwọn kò ni Ẹmí.

20. Ṣugbọn ẹnyin, olufẹ, ti ẹ ngbe ara nyin ró lori ìgbagbọ́ nyin ti o mọ́ julọ, ti ẹ ngbadura ninu Ẹmí Mimọ́,

21. Ẹ mã pa ara nyin mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun, ẹ mã reti ãnu Oluwa wa Jesu Kristi titi di iye ainipẹkun.

22. Ẹ mã ṣãnu awọn ẹlomiran, ẹ mã fi ìyatọ han:

23. Ẹ mã fi ẹ̀ru gba awọn ẹlomiran là, ẹ mã fà wọn yọ kuro ninu iná; ẹ tilẹ mã korira ẹ̀wu tí ara ti sọ di ẽri.

24. Njẹ ti ẹniti o le pa nyin mọ́ kuro ninu ikọsẹ, ti o si le mu nyin wá siwaju ogo rẹ̀ lailabuku pẹlu ayọ nla,

25. Ti Ọlọrun ọlọ́gbọn nikanṣoṣo, Olugbala wa, li ogo ati ọlá nla, ijọba ati agbara, nisisiyi ati titi lailai. Amin.

Jud 1