1. NIGBANA ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ̀ lati inu ẹja na wá,
2. O si wipe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, on si gbohùn mi; mo kigbe lati inu ipo-okú, iwọ si ti gbohùn mi.
3. Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi.
4. Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ.