9. On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ.
10. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru gidigidi, nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe eyi? nitori awọn ọkunrin na mọ̀ pe o sá kuro niwaju Oluwa, nitori on ti sọ fun wọn.
11. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Kini ki a ṣe si ọ, ki okun le dakẹ fun wa? nitori okun ru, o si jà ẹfufu lile.
12. On si wi fun wọn pe, Ẹ gbe mi, ki ẹ si sọ mi sinu okun; bẹ̃li okun yio si dakẹ fun nyin: nitori emi mọ̀ pe nitori mi ni ẹfufu lile yi ṣe de bá nyin.
13. Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn.