15. Bẹ̃ni nwọn gbe Jona, ti nwọn si sọ ọ sinu okun: okun si dẹkun riru rẹ̀.
16. Nigbana ni awọn ọkunrin na bẹ̀ru Oluwa gidigidi, nwọn si rubọ si Oluwa, nwọn si jẹ́ ẹ̀jẹ́.
17. Ṣugbọn Oluwa ti pese ẹja nla kan lati gbe Jona mì. Jona si wà ninu ẹja na li ọsan mẹta ati oru mẹta.