12. On si wi fun wọn pe, Ẹ gbe mi, ki ẹ si sọ mi sinu okun; bẹ̃li okun yio si dakẹ fun nyin: nitori emi mọ̀ pe nitori mi ni ẹfufu lile yi ṣe de bá nyin.
13. Ṣugbọn awọn ọkunrin na wà kikan lati mu ọkọ̀ wá si ilẹ; ṣugbọn nwọn kò le ṣe e: nitori ti okun ru, o si jà ẹfufu lile si wọn.
14. Nitorina nwọn kigbe si Oluwa nwọn si wi pe, Awa bẹ̀ ọ, Oluwa awa bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki awa ṣegbe nitori ẹmi ọkunrin yi, má si ka ẹjẹ alaiṣẹ si wa li ọrùn: nitori iwọ, Oluwa, ti ṣe bi o ti wù ọ.