1. NJẸ ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jona ọmọ Amittai wá, wipe,
2. Dide, lọ si Ninefe, ilu nla nì, ki o si kigbe si i; nitori ìwa buburu wọn goke wá iwaju mi.
3. Ṣugbọn Jona dide lati sá lọ si Tarṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Joppa; o si ri ọkọ̀ kan ti nlọ si Tarṣiṣi: bẹ̃li o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ sinu rẹ̀, lati ba wọn lọ si Tarṣiṣi lati sá kuro niwaju Oluwa.
4. Ṣugbọn Oluwa rán ẹfufu nla jade si oju okun, ijì lile si wà ninu okun, tobẹ̃ ti ọkọ̀ na dabi ẹnipe yio fọ.