Joh 8:6-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ.

7. Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u.

8. O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ.

9. Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà.

10. Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi?

11. O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹ̃li emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.

12. Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.

13. Nitorina awọn Farisi wi fun u pe, Iwọ njẹri ara rẹ; ẹrí rẹ kì iṣe otitọ.

14. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Bi mo tilẹ njẹri fun ara mi, otitọ li ẹrí mi: nitoriti mo mọ̀ ibiti mo ti wá, mo si mọ̀ ibiti mo nlọ; ṣugbọn ẹnyin kò le mọ̀ ibiti mo ti wá, ati ibiti mo nlọ.

15. Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni.

16. Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi.

17. Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji.

Joh 8