Joh 8:15-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ẹnyin nṣe idajọ nipa ti ara; emi kò ṣe idajọ ẹnikẹni.

16. Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi.

17. Ẹ si kọ ọ pẹlu ninu ofin nyin pe, otitọ li ẹrí enia meji.

18. Emi li ẹniti njẹri ara mi, ati Baba ti o rán mi si njẹri fun mi.

19. Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu.

20. Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.

Joh 8