48. O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́?
49. Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu.
50. Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn),
51. Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi?
52. Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili ndan? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.
53. Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.